Wonderous ways of God.
From CAC Gospel Hymn Book
1. Ona ara l‘Olorun wa
Ngba sise Re l‘aye;
A nri ‘pase Re lor‘okun,
O ngun igbi l‘esin.
2. Ona Re, enikan ko mo,
Awamaridi ni;
O pa ise ijinle mo,
Oba awon oba.
3. Ma beru mo, eyin mimo,
Orun to su be ni,
O kun fun anu yo rojo
Ibukun s‘ori yin.
4. Mase da Oluwa l‘ejo
Sugbon gbeke re le;
‘Gbati o ro pe O nbinu,
Inu Re yo si o.
5. Ise Re fere ye wa na,
Y‘o ma han siwaju;
Bi o tile koro loni,
O mbo wa dun lola.
6. Afoju ni alaigbagbo,
Ko mo ‘se Olorun;
Olorun ni Olutumo,
Y‘O m‘ona Re ye ni.
Amin
https://play.google.com/store/apps/details?id=com.adediranife.cachymn
Comments
Post a Comment